Keere O!

3 views

Lyrics

Àdan d'oríkodò (àdan d'oríkodò)
 Ó mí wò 'ṣe ẹyẹ (ó mí wò 'ṣe ẹyẹ)
 Tẹníbẹ'gi ló jù (tẹníbẹ'gi ló jù)
 Ṣé b'ígi á rú 'wé (ṣèb'ígi á rú 'wé)
 Ẹ má rò wọn pin o
 Eni ò rí ṣe l'òní
 Kò s'ẹ'ni t'ó m'ọla o
 Ìgbẹ'yìn l'aláyò ń ta o
 Yee, kéere o, ọba ló ní a ki yín
 Wọn ní ẹ má ṣ'ọlẹ o, ẹ múra sí iṣẹ' ajé
 Yee, kéerè o, ìjòyè ṣe yín pẹ'lẹ'
 Wọn ní ẹ má ṣ'àfara, ẹ jẹ' a tún ilẹ yí ṣe
 ♪
 Kéere o, kéere
 Ẹ bá ń ké sí wọn o (ẹ bá ń ké sí wọn o)
 Àwọn a fòró ìlú (àwọn a fòró ìlú)
 Akótilétà l'opọ (akótilétà l'opọ)
 Ọ'tá a ṣe bí ọrẹ (ọtá a ṣe bí ọrẹ)
 T'ẹ bá f'etí s'ílẹ'
 Sèbí irọ àtọdúnmọ'dún
 Òun ni wọn ń rò l'ọbẹ'
 Tí wọn fi nrùn wá n'ímú
 Yee, kéere o, àgbà ló ní a kí yín
 Wọn ní, "Ẹ má gbà mọ o, p'ọmọ àpà tún borí"
 Yee, keére o, ará ọ'run t'àjò dé
 Wọn ní a b'áwọn l'ọrùn, ka gb'òmìnira tòótọ'
 ♪
 Kéere o, kéere
 ♪
 Àdan d'oríkodò (àdan d'oríkodò)
 Ó mí wò 'ṣe ẹyẹ (ó mí wò 'ṣe ẹyẹ)
 Ọrọ yí ń dé kùn, d'áyà (ọrọ yí ń dé kùn, d'áyà)
 T'ó bá yá ojú á k'ojú (t'ó bá yá ojú á k'ojú)
 Yee, kéere o, ọba ló ní a ki yín
 Wọn ní e má ṣ'àníyàn, ká ṣ'ayé 're kó yẹ wá
 Yee, kéere o, ará ọ'run t'àjò dé
 Wọn ní ẹ b'ókùn l'ọ'rùn, ka d'òmìnira tòótọ'
 ♪
 Kéere o, kéere
 

Audio Features

Song Details

Duration
04:42
Tempo
89 BPM

Share

More Songs by Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band

Albums by Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band

Similar Songs