Moworesire
2
views
Lyrics
Onítibí yẹn ńlọ, ó mà ṣe bẹbẹ Ah, wọn l'óun t'ó ti gbé ṣe, ó mà tóbi o A-l'ọ'jọ, ọjọ' yẹn, ó ṣe kísà, ó ná'wó ná'ra Ọnà rèé, kálọ, ká fi hàn ọ La'jú rẹ sílẹ koo r'ẹ'yìn atanijẹ La'tí rẹ sílẹ, ko gb'ọrọ' òtítọ nì Ẹni nṣ'ọdún owó yẹn, ṣ'ó l'áyọ' nínú? Gbogbo òun tó ńdán kọ' ni wúrà o Jọwọ, m'ọwọrẹ sí're, ọrẹ, ṣè'wọn t'ápá rẹ bá ká, àbúrò Má ṣe wù'wà ìbàjẹ, má ṣe k'ẹ'gbẹ ọlọ'tẹ Ọnà tóró yẹn ló l'ádùn gan Jọwọ, m'ọwọrẹ sí're, ọrẹ, ṣè'wọn t'ápá rẹ bá ká, àbúrò Má ṣe mọ'dàrú, má ṣe k'ẹ'gbẹ ọlọ'bùn Ìwà rere yẹn ní if'ọkàn ẹni ba'lẹ ♪ Àgbà sọ fún wa ní'gbà ọdọ o, ẹni ire Wọn ló yẹ k'ọ'mọlúàbí ní ìtẹ'lọ'rùn Ká má fì'ka mẹ'wà jẹun lẹẹkan, t'àìgbọn kọ ni ká ṣe pẹlẹ Ẹni l'ọ'lá ìyẹn á mà bá'lẹ lọ Ẹni ò ní kò ní kọjá ọjọ tirẹ Ká má ṣe bí ọlọrọ tó gbàgbé ọgbọn Ìwa tó dára ló ga jù o Jọwọ, m'ọwọrẹ sí're, ọrẹ, ṣè'wọn t'ápá rẹ bá ká, àbúrò Má ṣe wù'wà ìbàjẹ, má ṣe k'ẹ'gbẹ ọlọ'tẹ Ọnà tóró yẹn ló l'ádùn gan Ah, jọwọ, m'ọwọrẹ sí're, ọrẹ, ṣè'wọn t'ápá rẹ bá ká, àbúrò Má ṣe mọ'dàrú, má ṣe k'ẹ'gbẹ ọlọ'bùn Ìwà rere yẹn ní if'ọkàn ẹni ba'lẹ ♪ M'ọwọrẹ sí're, ọrẹ, ṣè'wọn t'ápá rẹ bá ká, àbúrò Má ṣe wù'wà ìbàjẹ, má ṣe k'ẹ'gbẹ ọlọ'tẹ Ọnà tóró yẹn ló l'ádùn gan Ah, jọwọ, m'ọwọrẹ sí're, ọrẹ, ṣè'wọn t'ápá rẹ bá ká, àbúrò Má ṣe mọ'dàrú, má ṣe k'ẹ'gbẹ ọlọ'bùn Ìwà rere yẹn ní if'ọkàn ẹni ba'lẹ ♪ Onítibí yẹn ńlọ, ó mà ṣe bẹbẹ Ah, onítibí yẹn ńlọ, ó mà ṣe rere Ah, onítibí yẹn ńlọ, ó mà ṣe bẹbẹ Onítibí yẹn ńlọ, ó mà ṣe dada Onítibí yẹn ńlọ, ó mà ṣe bẹbẹ Onítibí yẹn ńlọ, ó mà ṣe rere
Audio Features
Song Details
- Duration
- 05:11
- Key
- 5
- Tempo
- 110 BPM
Share
More Songs by Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band
Albums by Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band
Similar Songs
Araromi
Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band
Atunda Ere
Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band
Gedegbe
Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band
Ijo Oni
Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band
Abanije
Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band
Afurugbin
Beautiful Nubia and the Roots Renaissance Band