Ikoko Akufo (Lamentation For A Broken Pot)

3 views

Lyrics

Ikoko akufo, o d'ero akitan o
 Ikoko to fo o, o ti dero akitan o
 Monomono ya lu'gi, oro wo 'nu ilu o
 Itiju bi aso akisa lo ma ri o
 O d'oro agbagba o, o d'eru f'ologbon
 O d'owo awon agba o, o d'eru f'ologbon
 ♪
 Ilu Orita o
 Ilu alaafia
 Mo ni t'e ba de'be
 E ba mi ki won o
 Gbogbo wa la o f'ayo de 'le
 Gbogbo wa la o f'ayo de 'le wa
 Mo ni t'e ba ri o
 E ba nki Awero yen o
 Omoge awelewa to nda ni l'orun o
 Ile owo ni o wo s'aya
 Ile ola ni o wo s'aya o
 ♪
 Seb'ade ori oko ni won
 Obinrin to n'iwa t'o l'ewa
 Iwuri obi ni won o ma je
 Mobinrin to gb'eko to mu lo
 Ori re dara, ori re sunwon, o d'adufe olori oko
 Ori re dara, ori re sunwon, o d'abefe o
 Ikoko to fo i s'oun a mu se'be
 Ikoko to fo i s'oun a mu to'le
 Ikoko to fo i s'oun a mu r'odo
 Ikoko to fo i s'oun a mu yan'gan
 Ibadi aran d'eni a mu se yeye o
 Bi eye ti o l'apa
 Ibadi aran d'eni a mu se yeye o
 O ba ma i lo o
 O ba ma i lo o
 Duro se'un obinrin nse
 O ba ma i lo o
 Awero o ba ma i lo o
 Gb'aye se'un obinrin nse
 O ba duro f'inu sh'oyun
 Duro se'un obinrin nse
 O ba gb'aye feyin gbomopon
 Gb'aye se'un obinrin nse
 O ba ma i lo o
 O ba ma i lo o
 Duro se'un obinrin nse
 ♪
 Ilu Orita o
 Ilu alaafia
 Mo ni t'e ba de'be
 E ba mi ki won o
 Gbogbo wa la o f'ayo de 'le
 Gbogbo wa la o f'ayo de 'le wa
 Mo ni t'e ba ri o
 E ba nki Awero yen o
 Omoge awelewa to nda ni l'orun o
 Ile owo ni o wo s'aya
 Ile ola ni o wo s'aya o
 

Audio Features

Song Details

Duration
05:30
Key
1
Tempo
163 BPM

Share

More Songs by Beautiful Nubia

Albums by Beautiful Nubia

Similar Songs