Matters Arising

3 views

Lyrics

Aaaah ah
 Ye a ma de o, a ma de o
 A wa n kilọ funra wa ni o
 Ye a ma de o, orẹ a tun de o
 Ẹ jẹ a ṣ'otitọ fun'rawa o
 Ye a ma de o, a ma de o
 A wa n kilọ funra wa ni o
 Ye a ma de o, orẹ a tun de o
 Ẹ jẹ a ṣ'otitọ fun'rawa o
 Iwọ gbẹsin sori, gbogbo ara ilu ti wa d'ẹlẹṣẹ loju rẹ
 Ẹyin gbẹsin leri, ẹ wa n paniyan l'orukọ Ọlọrun loke
 Ṣe iwọ ti gbagbe o
 Pe Ọlọrun ọba, Oluwa ifẹ ni kii korira
 Se ẹyin ti gbagbe o
 Pe Eledumare alagbara
 Ko le gbeja ara re, ye e-e
 Ye a ma de o, a ma de o
 A wa n kilọ funra wa ni o
 Ye a ma de o, orẹ a tun de o
 Ẹ jẹ a s'otitọ fun'rawa o
 Iwọ depo ọla, o wa n ṣiwa hu, o ti gbagbe orisun
 O n jaye olowo, ọmọde ilu n wọnu akitan kebi ma pa wọn o
 Ko le s'alaafia ninu ilu binu ara ilu o ba dun
 Ko le s'alaafia ọrẹ f'olowo fun talaka
 Ba o ba ṣ'otitọ ni'jọba o
 Ye a ma de o, a ma de o
 A wa n kilọ funra wa ni o
 Ye a ma de o, orẹ a tun de o
 Ẹ jẹ a ṣ'otitọ fun'rawa o
 Ọrẹ otitọ ṣọwọn o
 Ife otitọ ṣọwọn ye
 Oo le gbara l'ẹnikankan o
 Wọn a ba ẹ jẹ o, wọn a ba ẹ mu o
 To ba yẹyin pada, wọn a sọrọ ẹ ni buruku
 Wọn a ba ẹ logba, wọn a ba ẹ jẹ gbadun
 B'igba ba yi pẹnrẹn gbogbo wọn a sa lọ o
 Ilara ti pọju, ikorira ti pọju
 Ko le silọsiwaju ninu abosi
 Ikunsinu ti pọju atimọtẹni nikan
 Ko le silọsiwaju ninu iwa ibajẹ yii o
 Ọrẹ otitọ ṣọwọn o
 Ife otitọ ṣọwọn ye
 Oo le gbara l'ẹnikankan o
 Wọn a ba ẹ jẹ o, wọn a ba ẹ mu o
 To ba yẹyin pada, wọn a sọrọ ẹ ni buruku
 Wọn a ba ẹ logba, wọn a ba ẹ jẹ gbadun
 B'igba ba yi pẹnrẹn gbogbo wọn a sa lọ o
 Ilara ti pọju, ikorira ti pọju
 Ko le silọsiwaju ninu abosi
 Ikunsinu ti pọju atimọtẹni nikan
 Ko le silọsiwaju ninu iwa ibajẹ yii o
 O-o e-e

Audio Features

Song Details

Duration
08:35
Key
5
Tempo
122 BPM

Share

More Songs by Beautiful Nubia

Albums by Beautiful Nubia

Similar Songs